Afia Obinim,

Akoni Ọkunrin

Baba arugbo kan gbe ni ilu Ibadan. Obi omo meta - obirin meji ati okunrin kan.
Ni alaale baba arugbo yii ama so itan nipa ara re fun awon omo re.

"Eyin omo mi nigbati mo wa ni odo mo gbojugboya. Mo lakinkanju. Beeni mo si je akoni. Mo ma ngbegba oroke ninu gbogbo ija. Ko si si eranko kan ti nko leepa ninu igbo. Mo le sise takun takun"

Bi baba yi se nso oro lowo, okun kan ja latori aja sile. Logan ni baba fi ere gee ti osi sa pamo si eyin abikeyin re. Oke lohun rara si awon omo re:

"Epaa! Epaa! Etete pa ejo yii!"

"Baba kii se ejo. Okun lasan ni, Haaa! mo lero wipe eyin lenso bi ese ma npa orisirisi awon eranko nigbo?"

Baba dahun owipe: "Mo sese fe sofun yin wipe akinkanju mi ilu Ogbomoso lo mon. Ko pe ti mo de ilu Ibadan"